5 Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apákan tí ó sì doríkodò.
6 Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,Áà ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?
7 Rántí ìgbà láéláé;wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,àwọn àgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.
8 Nígbà tí atóbijù fi ogún àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn,nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàngẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.
9 Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,Jákọ́bù ni ìpín ìní i rẹ̀.
10 Ní ihà ni ó ti rí i,ní ihà níbi tí ẹranko kò sí.Ó yíká, ó sì tọ́jú u rẹ̀,ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.
11 Bí idì ti íru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ńrábàbà sórí ọmọ rẹ̀,tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sìgbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.