13 Ní ti Jóṣẹ́fù ó wí pé:“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrìàti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;
14 àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wáàti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
15 pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanìàti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
16 Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Jósẹ́fù,lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀.
17 Ní ọlá ńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀ èdè,pàápàá títí dé òpin ayé.Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúráímù,àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.”
18 Ní ti Ṣébúlúnì ó wí pé:“Yọ̀ Sébúlúnì, ní ti ìjáde lọ rẹ,àti ìwọ Ísákárì, nínú àgọ́ rẹ.
19 Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkèàti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkun,nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”