1 Nígbà náà ni Móṣè gun òkè Nébò láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù sí orí Písigà tí ó dojú kọ Jẹ́ríkò. Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gílíádì dé Dánì,
2 gbogbo Náfítanì, ilẹ̀ Éfúrámù àti Mánásè, gbogbo ilẹ̀ Júdà títí dé òkun ìwọ̀-oòrùn.
3 Gúṣù àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ dé Sóárì.
4 Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò débẹ̀.”