1 Mósè sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sì wí pé: Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etíìgbọ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n.
2 Olúwa Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú ní Hórébù.
3 Kì í ṣe àwọn baba wa ni Olúwa bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láàyè níbí lónìí.
4 Olúwa bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrin iná lórí òkè.