Ísíkẹ́lì 13:11-17 BMY

11 nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ̀ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, N ó sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀.

12 Nígbà tí odi náà bá sì wó, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn ò ní bi yín pé, “Rírẹ́ tí ẹ rẹ́ ẹ dà, ibo sì ni ẹfun tí ẹ fi kùn ún wà?”

13 “ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nínú ìbínú gbígbóná mi, èmi yóò tu afẹ́fẹ́ líle lée lórí nínú ìrunú mi, àti nínú ìbínú mi, òjò yóò sì rọ̀ púpọ̀ nínú ìbínú mi, àti yìnyín ńlá nínú ìrunú mi làti pa wọ́n run.

14 Èmi yóò wó ògiri tí ẹ fi amọ̀ àìpò rẹ́, èyí tí ẹ fi ẹfun kùn lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ yóò hàn jáde. Nígbà ti odi náà wó palẹ̀, a ó sì run yín sínú rẹ̀, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

15 Báyìí ni N ó ṣe lo ìbínú mi lórí odi yìí àti àwọn to fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, tí wọ́n sì fi ẹfun kùn ún. N ó sì sọ fún yín pé, “Kò sí odi mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó rẹ́ ẹ náà kò sí mọ́;

16 Àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tí ń sọtẹ́lẹ̀ nípa àlàáfíà nígbà ti kò sì àlàáfíà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí.” ’

17 “Nísinsin yìí, ọmọ ènìyàn, dojú kọ àwọn ọmọbìnrin ènìyàn rẹ tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, sọtẹ́lẹ̀ sí wọn