7 Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ sọ pé, “Olúwa wí,” bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀?
8 “ ‘Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí ọ̀rọ̀ asán àti ìran èké yín, mo lòdì sí yín: ni Olúwa Ọlọ́run wí.
9 Ọwọ́ mi yóò sì wà lórí àwọn wòlíì tó ń ríran asán, tó sì ń sọ àfọ̀ṣẹ èké. Wọn kò ní sí nínú ìjọ àwọn ènìyàn mi, a ó sì yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ̀ ilé Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́. Nígbà náà ni ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run.
10 “ ‘Wọ́n ti mú àwọn ènìyàn mi sìnà, wọ́n ní, “Àlàáfíà” nígbà tí kò sí àlàáfíà, nítorí pé bí àwọn ènìyàn bá mọ odi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ wọn a fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, wọn ó sì fi ẹfun kùn ún,
11 nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ̀ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, N ó sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀.
12 Nígbà tí odi náà bá sì wó, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn ò ní bi yín pé, “Rírẹ́ tí ẹ rẹ́ ẹ dà, ibo sì ni ẹfun tí ẹ fi kùn ún wà?”
13 “ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nínú ìbínú gbígbóná mi, èmi yóò tu afẹ́fẹ́ líle lée lórí nínú ìrunú mi, àti nínú ìbínú mi, òjò yóò sì rọ̀ púpọ̀ nínú ìbínú mi, àti yìnyín ńlá nínú ìrunú mi làti pa wọ́n run.