12 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
13 “Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀ èdè kan bá ṣẹ́ mí nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, n ó rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀,
14 bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí—Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù-tilẹ̀ wà nínú rẹ, ará wọn nìkan ni wọ́n lé gbà sílẹ̀ pẹ̀lú ìwà òdodo wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí.
15 “Tàbí bí mo bá jẹ́ kí ẹranko búburú gba orílẹ̀ èdè náà kọjá tí wọn fi sílẹ̀ láìní ọmọ tí wọ́n sì sọ di ahoro, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sẹ́ni tó le gba ibẹ̀ kọjá torí ẹranko búburú yìí,
16 bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí wà níbẹ̀ bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, wọn kò lé gba àwọn ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn là, ilẹ̀ náà yóò di ahoro.
17 “Tàbí tí mo bá mú idà kọjá láàrin orílẹ̀ èdè náà tí mo wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí idà kọjá láàrin ilẹ̀ náà,’ tí mo sì tú ìbínú gbígbóná lé wọn lórí nípa ìtàjẹ́sílẹ̀, tí mo pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ.
18 Bí àwọn ọkúnrin mẹ́ta yìí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run wí pé, Bí mo ti wà, wọn ki yóò gba ọmọkúnrin tàbí ọmọbìnrin là, ṣùgbọ́n àwọn tikara wọn nìkan ni a o gbàlà.