Ísíkẹ́lì 14:3-9 BMY

3 “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọnyìí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn. Ṣé ó tún yẹ kí n gbà wọ́n láàyè láti wádìí lọ́dọ̀ mi rárá bi? Nítorí náà, sọ fún wọn pé:

4 ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tó ó gbé òrìṣà sí ọkàn wọn, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ ṣíwájú rẹ̀, bá wá sọ́dọ̀ wòlíì, Èmi Olúwa fúnra mi ni n ó dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ.

5 N ó ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Ísírẹ́lì tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi.’

6 “Nítorí náà sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Ẹ ronú pìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀!

7 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sọ́kàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó ń mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ṣíwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi Olúwa fúnra ara mi ní ń o dá a lóhùn.

8 N ó lodi si írú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, n ó sì sọ ọ́ di àánú àti òwe. Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi. Nígbà náà, ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

9 “ ‘Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi Olúwa ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.