51 Samaríà kò ṣe ìdájìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arabìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe.
52 Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ. Torí náà rú ìtíjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo.
53 “ ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ padà ìgbèkùn àti Samaríà pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ, èmi yóò sì dá ìgbèkùn tirẹ̀ náà padà pẹ̀lú wọn
54 Kí ó bá à le rú ìtìjú rẹ, àti ẹ̀gàn gbogbo ohun tí ìwọ se láti tù wọ́n nínú.
55 Nígbà tí àwọn arábìnrin rẹ, Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ; Samaríà àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ba padà si ipò tí wọn wà tẹ́lẹ̀, ìgbà náà ni ìwọ náà yóò padà sí ipò àtijọ́ rẹ.
56 Iwọ ko tilẹ̀ ní dárúkọ arábìnrin rẹ Sódómù ni ọjọ́ ìgbéraga rẹ,
57 Kó tó di pé àsírí ìwà búburú rẹ tú síta, báyìí ìwọ di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Édómù Síríà àti gbogbo agbègbè rẹ àti lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Fílístínì àti lọ́dọ̀ àwọn tó yí ọ ká, ti wọn si ń kẹ́gàn rẹ.