Ísíkẹ́lì 17:16-22 BMY

16 “ ‘Bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí, níbi tí Ọba tó fi sórí oyè wà, ẹ̀jẹ́ ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà, níbẹ̀ ni àárin Bábílónì ní yóò kùú sí.

17 Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, Fáráò pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún-un lójú ogun.

18 Nítorí pé ó kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kò ní i bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan to ṣe yìí.

19 “ ‘Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run wí pé: Bí mo ti wà láàyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀.

20 Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, N ó mú ọ lọ Bábílónì láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi.

21 Gbogbo ìsáǹsá àti ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi Olúwa lo sọ̀rọ̀.”

22 “ ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lori igi Kédàrí gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó sẹ̀sẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí.