1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Kín ni ẹ̀yín rò tí ẹ̀yin fi ń pa òwe nípa Ísírẹ́lì wí pé:“ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà kíkan,eyín àwọn ọmọ sì kan.’
3 “Bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí, ẹ̀yin kó ni i pa òwe yìí mọ́ ni Ísírẹ́lì.
4 Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápá jẹ tèmi, ọkàn tó bá sẹ̀ ní yóò kú.