1 Ní ọjọ kẹ́wàá, oṣù kàrùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbà Ísírẹ́lì wá wádìí lọ́wọ́ Olúwa, wọn jòkòó níwájú mi.
2 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
3 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbà Ísírẹ́lì, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí. N ò ní í gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’
4 “Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí? Ìwọ fẹ dájọ́ wọn bí ọmọ ènìyàn? Nítorí náà fi gbogbo ìwà ìríra baba wọn kò wọ́n lójú,
5 kí ó sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Ní ọjọ tí mo yàn Ísírẹ́lì, mo gbé ọwọ́ mi ṣokè nínú ẹ̀jẹ́ sí àwọn ọmọ ilé Jákọ́bù, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Éjíbítì, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
6 Ní ọjọ́ náà mo lọ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn pé ń ó mú wọn kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù.