Ísíkẹ́lì 20:12-18 BMY

12 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí àmì láàrin àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.

13 “ ‘Síbẹ̀; ilé Ísírẹ́lì sọ̀tẹ̀ sí mí nínú ihà. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀-bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè è nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, ń ó sì pa wọ́n run nínú ihà.

14 Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè tí mo kó wọn jáde lójú wọn.

15 Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn nínú ihà pé ń kò ní i mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù.

16 Nítorí pé wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àsẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn.

17 Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú ihà.

18 Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú ihà pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín tàbí kí ẹ pa òfin wọn mọ́ tàbí kí ẹ bara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn.