6 Ní ọjọ́ náà mo lọ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn pé ń ó mú wọn kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù.
7 Mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ẹ̀ni kọ̀ọ̀kan yín mú àwọn àwòrán ìríra ti ẹ gbé ṣíwájú yín kúrò, kí ẹ sì má bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìsà Éjíbítì, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
8 “ ‘Ṣùgbọ́n wọn sọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́ràn, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojú kọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Éjíbítì sílẹ̀, torí náà mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, ń ó sì jẹ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì.
9 Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè tí wọn ń gbé láàrin wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Ísírẹ́lì nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Éjíbítì.
10 Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Éjíbítì mo sì mú wọn wá sínú ihà.
11 Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítori pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn.
12 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí àmì láàrin àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.