5 Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà, yóò fi ọ se ẹlẹ́yà, Áà! ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá.
6 “ ‘Wo bí ìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ọba Ísírẹ́lì tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀.
7 Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwà-kúwà sí aláìní baba àti opó.
8 Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkúlò.
9 Nínú rẹ ni àwọn ayanijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́.
10 Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọla fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn ti o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́.
11 Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ ṣe, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀.