1 Ní ọjọ kìn-ín-ní, oṣù kọ́kànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tírè sọ nípa Jérúsálẹ́mù pé, ‘Áà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’
3 nítorí náà, báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, èmí dojú kọ ọ́ ìwọ Tírè, Èmi yóò sì jẹ́ kí orílẹ̀ èdè púpọ̀ dide sí ọ, gẹ́gẹ́ bí òkun tíi ru sókè.
4 Wọn yóò wó odi Tírè lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀; Èmi yóò sì ha ẹrùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.
5 Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàárin òkun, ní Olúwa Ọlọ́run wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀ èdè.