1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé:
2 “Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Pohùnréré ẹkún kí o sì wí pé,“Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”
3 Nítorí ọjọ́ náà sún mọ́ tòsíàní ọjọ́ Olúwa sún mọ́ tòsíỌjọ́ tí ọjọ́ ìkùukùu ṣú dúdú,àsìkò ìparun fún àwọn aláìkọlà
4 Idà yóò wá sórí Éjíbítììrora ńlá yóò sì wá sórí KúṣìNígbà tí àwọn tí a pa yóò subú ní Éjíbítìwọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.
5 Kúṣì àti Pútì, Lídíà àti gbogbo Árábù, Líbíyà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ìlérí yóò ṣubú nípa idà papọ̀ pẹ̀lú Éjíbítì.