Ísíkẹ́lì 34:2-8 BMY

2 “Ọmọ ènìyàn, fí àsọtẹ́lẹ̀ tako olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì; sọ tẹ́lẹ̀ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ègbé ni fún olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́ àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran?

3 Ìwọ jẹ wàrà. O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran.

4 Ìwọ kò ì tíì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa. Ìwọ kò í tíì mú aṣàko padà tàbí wá ẹni tí ó nù. Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò.

5 Nítorí náà wọn fọ́n káàkiri nítorí àìsí olùsọ́ àgùntàn, nígbà tí wọ́n fọ́n ká tán wọn di ìjẹ fún gbogbo ẹranko búburú.

6 Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn.

7 “ ‘Nítorí náà, ìwọ olùṣọ́ àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa:

8 Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, nitorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́ àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò ṣe awárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi,