4 Èmì yóò pa àwọn ìlú rẹ run, ìwọ yóò sì di ahoro. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
5 “ ‘Nítorí ìwọ dá ààbò bo ọ̀tẹ̀ àtayébáyé, tí ìwọ sì fi Ísírẹ́lì lé idà lọ́wọ́, ní àsìkò ìdààmú wọn, ní àsìkò tí ìjìyà wọn dé góńgó,
6 nítorí náà bi mo ti wà láàyè, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò fi ọ kalẹ̀ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. Níwọ̀n ìgbà tí ìwọ kò ti korìíra ìtàjẹ̀-sílẹ̀, ìtàjẹ̀-sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ.
7 Èmi yóò mú kí òkè Séírì di ahoro; ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ńlọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ.
8 Èmi yóò fi àwọn tí a pa kún orí òkè rẹ: àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú ní orí òkè rẹ, àti ní àárin àwọn òkè rẹ.
9 Èmi yóò mú kí o di ahoro títí láé; Kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
10 “ ‘Nítorí tí ìwọ sọ pé, “Àwọn orílẹ̀ èdè àti ilẹ̀ méjì wọ̀nyí yóò jẹ́ tiwa, àwa yóò sì gbà wọ́n ní ìní,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi Olúwa wà níbẹ̀,