Ísíkẹ́lì 36:19-25 BMY

19 Mo tú wọn ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn.

20 Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fí ilẹ̀ náà sílẹ̀.’

21 Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Ísírẹ́lì sọ di aláìmọ́ ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti lọ.

22 “Nítorí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti lọ.

23 Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárin wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀ èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.

24 “ ‘Nítorí èmi yóò mú yín jáde kúrò ni àwọn orílẹ̀ èdè náà; Èmi yóò ṣà yín jọ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú náà; Èmi yóò sì mú yín padà sí ilẹ̀ ẹ̀yin tìkarayín.

25 Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin.