Ísíkẹ́lì 36:32-38 BMY

32 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì!

33 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ iwólulẹ̀

34 ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́.

35 Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ṣíṣòfo tẹ́lẹ̀ ti dà bí ọgbà Édẹ́nì; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsìnyí.”

36 Nígbà náà àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfò gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’

37 “Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Ísírẹ́lì, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí àgùntàn,

38 Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jérúsálẹ́mù ní àsìkò àjọ. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”