Ísíkẹ́lì 36:6-12 BMY

6 Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kékèké, sí àwọn àfonífojì ńlá àti sí àwọn àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀ èdè.

7 Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀ èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.

8 “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Ísírẹ́lì, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí.

9 Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́,

10 èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a óò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́.

11 Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa.

12 Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, rìn lórí rẹ̀. Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn; ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́.