1 “Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ sí Gógù, kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gógì, olórí ọmọ-aládé ti Mésékì àti Túbálì.
2 Èmi yóò dá ọ padà, èmi yóò sì darí rẹ. Èmi yóò mú ọ wá láti jìnnàjìnnà ìhà àríwá, Èmi yóò rán ọ lòdì sí orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì.
3 Nígbà náà èmi yóò lu ọrùn awọ rẹ ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ jábọ́ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
4 Ìwọ yóò sì subú ní orí àwọn òkè Ísírẹ́lì, ìwọ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn onírúurú ẹyẹ àti fún àwọn ẹranko igbó.
5 Iwọ yóò ṣubú ní gbangba pápá, nítorí tì mo ti sọ̀rọ̀, ni Olúwa Ọba wí.
6 Èmi yóò fi iná sí mágógì àti sí àwọn tí ń gbé ní agbègbè ilẹ̀ ibẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.