1 “Nísinsìnyìí, Ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán Jérúsálẹ́mù sí orí rẹ̀.
2 Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká.
3 Kí o sì fi páànù irin kan ṣe ògiri láàrin rẹ̀ àti ìlú yìí, dojú kọ ọ́, kí o sì gbógun tì í. Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Ísírẹ́lì.
4 “Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dúbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì lé orí ara rẹ. Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
5 Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).