1 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi lọ sí ìta ibi mímọ́, ó sì wọn àwọn àtẹ́rígbà náà; ìbú atẹrígbà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ègbẹ́ kọ̀ọ̀kan.
2 Ẹnu ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ ògiri ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Ó sì wọn ìta ibi mímọ́ bákan náà; ó jẹ́ ogójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀.
3 Lẹ́yìn náà ó lọ sí inú yàrá ibi mímọ́, ó sì wọn àtẹ́rígbà àbáwọlé: ìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni fífẹ̀. Àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ ògiri àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ni fífẹ̀.
4 O sì wọn gígùn inú yàrá ibi mímọ́; o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ títí dé ìparí ìta ibi mímọ́. O sì sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi mímọ́ jùlọ.”