Ísíkẹ́lì 44:24-30 BMY

24 “ ‘Nínú èyíkéyi èdè-àìyedè, àwọn Àlùfáà ní ó gbọdọ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ fún gbogbo àṣẹ, wọn sì gbọdọ̀ lo ọjọ ìsinmi mi ní mímọ́.

25 “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn; ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ bàbá tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.

26 Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje.

27 Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti se ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Ọba wí.

28 “ ‘Èmi ni kì ó jẹ́ ogún tí àwọn Àlùfáà yóò ní. Ẹ kò gbọdọ̀ fún wọn ni ìpín kankan ní Ísírẹ́lì; Èmi ni yóò jẹ́ ìpín wọn.

29 Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ti wọn.

30 Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ti ẹ̀bùn pàtàkì yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ní láti fún wọn ní ìpín àkọ́kọ́ nínú èso ilẹ̀ yìí kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yìí.