22 Ní ọjọ́ náà ní ọmọ aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀sẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà.
23 Ní ojoojúmọ́ ni àárin ọjọ́ méje àṣè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
24 Òun yóò sì pèsè éfà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Éfà kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti éfà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan.
25 “ ‘Láàárin ọjọ́ méje àṣè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù kéje, òun yóò tún pèsè nǹkan bí ti tẹ́lẹ̀, fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú òróró.