10 “Ọjọ́ náà ti dé! O ti dé: Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tan ná, ìgbéraga ti sọ jáde!
11 Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú; kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kú, tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, kò sí ọrọ̀ ko si ohun ti o niye.
12 Àsìkò náà ti tó; ọjọ́ náà tidé, kí ẹni tó n rajà má se yọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ki ontàjà má ṣe ṣọ̀fọ̀; torí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
13 Nítorí pé ontàjà kò ni ri ilé tó tà gbà níwọ̀n ìgbà ti awọ̀n méjèèjì bá wà láyé; torí ìran tó kan ènìyàn yìí kò ní yí padà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là.
14 Bí wọn tilẹ̀ fọn fèrè ogun tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, kò sẹ́ni tí yóò lọ ojú ogun, torí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn
15 “Idà wà níta, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹní tó bá wà ní orílẹ èdè, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.
16 Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedédé rẹ̀.