12 Láti ọ̀dọ̀ Dánì, Áhíésérì ọmọ Ámísádáì;
13 Láti ọ̀dọ̀ Áṣérì, Págíélì ọmọ Ókíránì;
14 Láti ọ̀dọ̀ Gáádì, Élíásàfu ọmọ Déúélì;
15 Láti ọ̀dọ̀ Náfítalì, Áhírà ọmọ Énánì.”
16 Àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Ísírẹ́lì.
17 Mósè àti Árónì mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí
18 wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Ísírẹ́lì jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì se àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè,