46 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín-àádọ́ta, (603,550).
47 A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Léfì mọ́ àwọn ìyókù.
48 Nítorí Olúwa ti sọ fún Mósè pé,
49 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Léfì, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:
50 Dípò èyí yan àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ alábojútó àgọ́. Ẹrí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójú tó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká.
51 Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, àwọn ọmọ Léfì ni yóò tu palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Léfì náà ni yóò ṣe é. Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á
52 kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀.