1 Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etíìgbọ́ Olúwa. Ìbúnú Olúwa sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí, Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa bọ́ sí àárin wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó.
2 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn kígbe sí Mósè, Mósè sì gbàdúrà sí Olúwa iná náà sì kú.
3 Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tàbérà torí pé iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa jó láàrin wọn.
4 Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ́ wọn fi ìtara bèèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí!
5 Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Éjíbítì, apálá, ègúsí, ewébẹ̀ àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn