28 Sọ fún wọn, Bí Mo ti wà láàyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín.
29 Nínú ihà yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yín tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà.
30 Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra láti fi ṣe ilẹ̀ yín, àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jósúà ọmọ Núnì.
31 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀.
32 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní ihà yìí.
33 Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú ihà fun ogójì ọdún (40) wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní ihà.
34 Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi.