4 Kó wọn sí Àgọ́ Ìpàdé níwájú Ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín.
5 Ọ̀pá tí ó bá yí jẹ́ ti ẹni tí èmi bá yàn yóò rú wé, èmi yóò sì dá kíkùn gbogbo ìgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí yín dúró.”
6 Nígbà náà Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn sì fún un ní ọ̀pá méjìlá, ọ̀pá kan fún olórí kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ìran wọn, ọ̀pá Árónì sì wà lára àwọn ọ̀pá náà.
7 Mósè sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.
8 Ó sì se ní ọjọ́ kéjì Mósè wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Árónì, tí ó dúró fún ẹ̀yà Léfì, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan Ṣùgbọ́n ó ruwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso jíjẹ.
9 Nígbà náà ni Mósè kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.
10 Olúwa sọ fún Mósè pé, “Mú ọ̀pá Árónì padà wá ṣíwájú Ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmìn fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má baà kú.”