22 Ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni yóò tẹ̀ lé e. Olórí Bẹ́ńjámínì ni Ábídánì ọmọ Gídíónì.
23 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tadínlógún ó lé egbéje (35,400).
24 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Éfúráímù, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàdọ́ta-ó-lé-ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.
25 Ní ìhà àríwá, ni ìpín Dánì yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olóri Dánì ni Áyésérì ọmọ Ámíṣádáyì.
26 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin. (62,700).
27 Ẹ̀yà Ásérì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ásérì ni Págíélì ọmọ Ókíránì.
28 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).