Nọ́ḿbà 20:14-20 BMY

14 Mósè sì ránṣẹ́ láti Kádésì sí ọba Édómù, wí pé:“Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Ísírẹ́lì sọ: Ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa.

15 Àwọn bàbá ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Éjíbítì ni wá lára àti àwọn bàbá wa,

16 ṣùgbọ́n nígbà tí a sunkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán ańgẹ́lì kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Éjíbítì.“Báyìí àwa wà ní Kádésì, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ.

17 Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀ èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kàǹga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.”

18 Ṣùgbọ́n Édómù dáhùn pé:“Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun síyín a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”

19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáhùn pé:“A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkankan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”

20 Wọ́n tún dáhùn wí pé:“Ẹ kò lè kọjá.”Nígbà náà ni Édómù jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ ogun.