20 Wọ́n tún dáhùn wí pé:“Ẹ kò lè kọjá.”Nígbà náà ni Édómù jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ ogun.
21 Nígbà tí Édómù sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Ísírẹ́lì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
22 Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì jáde láti Kádésì wọ́n sì wá sí orí òkè Hórì.
23 Ní orí òkè Hórì, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Édómù Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,
24 “Árónì yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Méríbà.
25 Mú Árónì àti ọmọ rẹ̀ Élíásárì lọ sí orí òkè Hórì.
26 Bọ́ aṣọ Árónì kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, nítorí pé Árónì yóò kú ṣíbẹ̀.”