26 Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì.
27 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó sì jókó ní abẹ́ Bálámù, inú sì bí i tó sì ná-àn pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀.
28 Nígbà náà Olúwa sí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Bálámù pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?”
29 Bálámù sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ì bá pa ọ́ nísinsin yìí.”
30 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Bálámù pé, “Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”“Rárá,” Ó dáhùn.
31 Nígbà náà Olúwa sí ojú Bálámù, ó sì rí ángẹ́lì Olúwa tí ó dúró ní oju ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fàyọ. Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba.
32 Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí? Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi.