1 Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-àrùn Olúwa sọ fún Mósè àti Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà pé
2 “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Ísírẹ́lì.”
3 Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Móábù pẹ̀lú Jọ́dánì tí ó kọjá Jẹ́ríkò, Mósè àti Élíásárì àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,
4 “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè.”Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde láti Éjíbítì wá: