56 Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrin ńlá àti kékeré.”
57 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Léfì tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Gáṣónì, ìdílé àwọn ọmọ Gáṣónì;ti Kóhátì, ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì;ti Mérárì, ìdílé àwọn ọmọ Mérárì.
58 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Léfì;ìdílé àwọn ọmọ Líbínì,ìdílé àwọn ọmọ Hébírónì,ìdílé àwọn ọmọ Málì,ìdílé àwọn ọmọ Múṣì,ìdílé àwọn ọmọ Kórà.(Kóhátì ni baba Ámírámù,
59 Orúkọ aya Ámírámù sì ń jẹ́ Jókébédì, ọmọbìnrin Léfì, tí ìyá rẹ̀ bí fún Léfì ní Éjíbítì. Òun sì bí Árónì, Mósè, àti Míríámù arábìnrin wọn fún Ámírámù.
60 Árónì ni baba Nádábù àti Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.
61 Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)
62 Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Léfì láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.