58 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Léfì;ìdílé àwọn ọmọ Líbínì,ìdílé àwọn ọmọ Hébírónì,ìdílé àwọn ọmọ Málì,ìdílé àwọn ọmọ Múṣì,ìdílé àwọn ọmọ Kórà.(Kóhátì ni baba Ámírámù,
59 Orúkọ aya Ámírámù sì ń jẹ́ Jókébédì, ọmọbìnrin Léfì, tí ìyá rẹ̀ bí fún Léfì ní Éjíbítì. Òun sì bí Árónì, Mósè, àti Míríámù arábìnrin wọn fún Ámírámù.
60 Árónì ni baba Nádábù àti Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.
61 Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)
62 Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Léfì láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.
63 Àwọn wọ̀nyí ni Mósè àti Élíásárì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá odò Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.
64 Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mósè àti Árónì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ihà Sínáì.