2 Wọ́n súnmọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mósè, àti Élíásérì àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé,
3 “Baba wa kú sí ihà. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, Ṣùgbọ́n ó kú nítórí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.
4 Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítórí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn arakùnrin baba wa.”
5 Nígbà náà Mósè mú ọ̀rọ̀ wọn wá ṣíwájú Olúwa.
6 Olúwa sì wí fún un pé,
7 “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣélófénátì ń sọ tọ̀nà. Ó gbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.
8 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀.