5 Lẹ́yin náà, wọn ẹgbẹ̀ẹ́dogun (3000) ẹṣẹ̀ bàtà lápá ibi ìhà ìlà oòrùn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ẹṣẹ̀ bàtà ní ìhà gúsù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àríwá. Pẹ̀lú ìlú ní àárin. Wọn yóò ní agbégbé yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.
6 “Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ ìlú ibi ìsásí, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì (42) ìlú sí i.
7 Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì ní éjìdínláàdọ́ta (48) ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
8 Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”
9 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé,
10 “Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jọ́dánì sí Kénánì,
11 Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sá lọ síbẹ̀.