6 Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Ṣélófíhádì: Wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.
7 Kò sí ogún kan ní Ísírẹ́lì tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ babańlá wọn pamọ́.
8 Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì lè ní ìpín nínú ogún baba wọn.
9 Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”
10 Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Ṣẹ́lófẹ́hádì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.
11 Nítorí pé a gbé Málà, Tírísà, Hógílà, Mílíkà, àti Nóà, àwọn ọmọbìnrin Ṣélófẹ́hádì ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn.
12 Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìrán Mánásè, ọmọ Jóṣẹ́fù ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn.