1 Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:
2 “Ka iye àwọn ọmọ Kóhátì láàrin àwọn ọmọ Léfì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.
3 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé.
4 “Wọ̀nyí ni iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ.
5 Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí.
6 Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.