26 Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà, okùn àti àwọn ohun èlò mìíràn tí à ń lò fún gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí. Àwọn ọmọ Gáṣónì ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí.
27 Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gáṣónì yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un.
28 Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gáṣónì ni Àgọ́ Ìpàdé Ítamárì, ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn.
29 “Ka iye àwọn ọmọ Mérárì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.
30 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.
31 Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú Àgọ́ Ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀,
32 Pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un;