28 Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ.
29 “ ‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe aṣemá ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́
30 Tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó fura sí ìyàwó rẹ̀. Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un.
31 Ara ọkọ rẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣùgbọ́n obìnrin náà yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’ ”