15 “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé.
16 Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátapáta nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkunrin gbogbo Ísírẹ́lì.
17 Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi.
18 Mo sì ti gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Isireli
19 Nínú Ísírẹ́lì, mo fi àwọn ọmọ Léfì fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-àrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́.”
20 Mósè, Árónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì ṣe fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.
21 Àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Árónì sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa, Árónì sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.