4 Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́.
5 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní ihà Ṣínáì ní ìdajì ọjọ́ kẹ́rìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.
6 Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mósè àti Árónì lọ́jọ́ náà.
7 Wọ́n sọ fún Mósè pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ará Ísírẹ́lì yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.”
8 Mósè sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pa láṣẹ nípa yín.”
9 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé,
10 “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá mọ́.