1 Lẹ́yìn ikú Jóṣúà, ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé “Èwo nínú ẹ̀yà wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ bá àwọn ará Kénánì jagun fún wa?”
2 Olúwa sì dáhùn pé, “Júdà ni yóò lọ; nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”
3 Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Júdà béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣíméónì arákùrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kénánì jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ ogun Síméónì sì bá àwọn ọmọ ogun Júdà lọ.
4 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Júdà sì kọ lu àwọn ọmọ Kénánì, Olúwa ran àwọn Júdà lọ́wọ́, ó sì fi àwọn ará Kénánì àti àwọn ará Párísì lé wọn lọ́wọ́, àwọn Júdà sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Béṣékì nínú àwọn ọ̀ta wọn.