Onídájọ́ 1:2-8 BMY

2 Olúwa sì dáhùn pé, “Júdà ni yóò lọ; nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”

3 Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Júdà béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣíméónì arákùrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kénánì jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ ogun Síméónì sì bá àwọn ọmọ ogun Júdà lọ.

4 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Júdà sì kọ lu àwọn ọmọ Kénánì, Olúwa ran àwọn Júdà lọ́wọ́, ó sì fi àwọn ará Kénánì àti àwọn ará Párísì lé wọn lọ́wọ́, àwọn Júdà sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Béṣékì nínú àwọn ọ̀ta wọn.

5 Ní Béṣékì ni wọ́n ti rí Adoni-Bésékì (Olúwa mi ní Béṣékì), wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kénánì àti Párísì.

6 Ọba Adoni-Bésékì sá àṣálà, ṣùgbọ́n ogun Ísírẹ́lì lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀.

7 Nígbà náà ni ó wí pé, àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń sa ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Olúwa ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn, wọ́n sì mú un wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kú sí bẹ̀.

8 Àwọn ológun Júdà sì ṣẹ́gun Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.